Yorùbá Bibeli

Luk 9:25-38 Yorùbá Bibeli (YCE)

25. Nitoripe ère kini fun enia, bi o jère gbogbo aiye, ti o si sọ ara rẹ̀ nù, tabi ki o fi ara rẹ̀ ṣòfò.

26. Nitori ẹnikẹni ti o ba tiju mi, ati ọ̀rọ mi, oju rẹ̀ li Ọmọ-enia yio si tì, nigbati o ba de inu ogo tirẹ̀, ati ti baba rẹ̀, ati ti awọn angẹli mimọ́.

27. Ṣugbọn emi wi fun nyin nitõtọ, ẹlomiran duro nihinyi, ti kì yio ri ikú, titi nwọn o fi ri ijọba Ọlọrun.

28. O si ṣe bi iwọn ijọ kẹjọ lẹhin ọ̀rọ wọnyi, o mu Peteru, ati Johanu, ati Jakọbu, o gùn ori òke lọ lati gbadura.

29. Bi o si ti ngbadura, àwọ oju rẹ̀ yipada, aṣọ rẹ̀ si fun lawu, o njo fòfo.

30. Si kiyesi i, awọn ọkunrin meji, ti iṣe Mose on Elijah, nwọn mba a sọ̀rọ:

31. Ti nwọn fi ara hàn ninu ogo, nwọn si nsọ̀rọ ikú rẹ̀, ti on ó ṣe pari ni Jerusalemu.

32. Ṣugbọn oju Peteru ati ti awọn ti mbẹ lọdọ rẹ̀ wuwo fun õrun. Nigbati nwọn si tají, nwọn ri ogo rẹ̀, ati ti awọn ọkunrin mejeji ti o ba a duro.

33. O si ṣe, nigbati nwọn lọ kuro lọdọ rẹ̀, Peteru wi fun Jesu pe, Olukọni, o dara fun wa ki a mã gbé ihinyi: jẹ ki awa ki o pa agọ́ mẹta; ọkan fun iwọ, ati ọkan fun Mose, ati ọkan fun Elijah: kò mọ̀ eyi ti o nwi.

34. Bi o ti nsọ bayi, ikũkũ kan wá, o ṣiji bò wọn: ẹ̀ru si ba wọn nigbati nwọn nwọ̀ inu ikuku lọ.

35. Ohùn kan si ti inu ikũkũ wá, o ni, Eyiyi li ayanfẹ Ọmọ mi: ẹ mã gbọ́ tirẹ̀.

36. Nigbati ohùn na si dakẹ, Jesu nikanṣoṣo li a ri. Nwọn si pa a mọ́, nwọn kò si sọ ohunkohun ti nwọn ri fun ẹnikẹni ni ijọ wọnni.

37. O si ṣe, ni ijọ keji, nigbati nwọn sọkalẹ lati ori òke wá, ọ̀pọ awọn enia wá ipade rẹ̀.

38. Si kiyesi i, ọkunrin kan ninu ijọ kigbe soke, wipe, Olukọni, mo bẹ̀ ọ, wò ọmọ mi; nitori ọmọ mi kanṣoṣo na ni.