Yorùbá Bibeli

Luk 8:35-45 Yorùbá Bibeli (YCE)

35. Nigbana ni nwọn jade lọ iwò ohun na ti o ṣe; nwọn si tọ̀ Jesu wá, nwọn si ri ọkunrin na, lara ẹniti awọn ẹmi èṣu ti jade lọ, o joko lẹba ẹsẹ Jesu, o wọṣọ, iyè rẹ̀ si bọ̀ si ipò: ẹ̀ru si ba wọn.

36. Awọn ti o ri i si ròhin fun wọn bi o ti ṣe ti a fi mu ẹniti o li ẹmi èṣu larada.

37. Nigbana ni gbogbo enia lati ilẹ Gadara yiká bẹ̀ ẹ pe, ki o lọ kuro lọdọ wọn; ẹ̀ru sá ba wọn gidigidi: o si bọ sinu ọkọ̀, o pada sẹhin.

38. Njẹ ọkunrin na ti ẹmi èṣu jade kuro lara rẹ̀, o bẹ̀ ẹ ki on ki o le ma bá a gbé: ṣugbọn Jesu rán a lọ, wipe,

39. Pada lọ ile rẹ, ki o si sọ ohun ti Ọlọrun ṣe fun ọ bi o ti pọ̀ to. O si lọ, o si nròhin já gbogbo ilu na bi Jesu ti ṣe ohun nla fun on to.

40. O si ṣe, nigbati Jesu pada lọ, awọn enia tẹwọgbà a: nitoriti gbogbo nwọn ti nreti rẹ̀.

41. Si kiyesi i, ọkunrin kan ti a npè ni Jairu, ọkan ninu awọn olori sinagogu, o wá: o si wolẹ lẹba ẹsẹ Jesu, o bẹ̀ ẹ pe, ki o máṣai wá si ile on:

42. Nitori o ni ọmọbinrin kanṣoṣo, ọmọ ìwọn ọdún mejila, o nkú lọ. Bi o si ti nlọ awọn enia nhá a li àye.

43. Obinrin kan ti o si ni isun ẹ̀jẹ lati igba ọdún mejila, ti o ná ohun gbogbo ti o ni fun awọn oniṣegun, bẹ̃ni a ko le mu u larada lati ọwọ́ ẹnikan wá,

44. O wá lẹhin rẹ̀, o fi ọwọ́ tọ́ iṣẹti aṣọ rẹ̀: lọgan ni isun ẹ̀jẹ rẹ̀ si ti gbẹ.

45. Jesu si wipe, Tali o fi ọwọ́ tọ́ mi? Nigbati gbogbo wọn sẹ́, Peteru ati awọn ti mbẹ lọdọ rẹ̀ wipe, Olukọni, awọn enia nhá ọ li àye, nwọn si mbilù ọ, iwọ si wipe, Tali o fi ọwọ́ kàn mi?