Yorùbá Bibeli

Luk 8:21-30 Yorùbá Bibeli (YCE)

21. O si dahùn o si wi fun wọn pe, Iya mi ati awọn arakunrin mi li awọn wọnyi ti nwọn ngbọ́ ọ̀rọ Ọlọrun, ti nwọn si nṣe e.

22. O si ṣe ni ijọ kan, o si wọ̀ ọkọ̀ kan lọ ti on ti awọn ọmọ-ẹhin rẹ̀: o si wi fun wọn pe, Ẹ jẹ ki awa ki o rekọja lọ si ìha keji adagun. Nwọn si ṣikọ̀ lọ.

23. Bi nwọn si ti nlọ, o sùn; iji nla si de, o nfẹ li oju adagun; nwọn si kún fun omi, nwọn si wà ninu ewu.

24. Nwọn si tọ̀ ọ wá, nwọn si jí i, wipe, Olukọni, Olukọni, awa gbé. Nigbana li o dide, o si ba ẹfufu on riru omi wi: nwọn si da, idakẹ-rọrọ si de.

25. O si wi fun wọn pe, Igbagbọ́ nyin dà? Bi ẹ̀ru ti mba gbogbo wọn, ti hà si nṣe wọn, nwọn mbi ara wọn pe, irú ọkunrin kili eyi! nitori o ba ẹfufu on riru omi wi, nwọn si gbọ́ tirẹ̀.

26. Nwọn si gúnlẹ ni ilẹ awọn ara Gadara, ti o kọju si Galili.

27. Nigbati o si sọkalẹ, ọkunrin kan pade rẹ̀ li ẹhin ilu na, ti o ti ni awọn ẹmi èṣu fun igba pipẹ, ti kì iwọ̀ aṣọ, bẹ̃ni kì ijoko ni ile kan, bikoṣe ni ìboji.

28. Nigbati o ri Jesu, o ke, o wolẹ niwaju rẹ̀, o wi li ohùn rara, pe, Kini ṣe temi tirẹ Jesu, iwọ Ọmọ Ọlọrun Ọgá-ogo? emi bẹ̀ ọ máṣe da mi loró.

29. (Nitoriti o ti wi fun ẹmi aimọ́ na pe, ki o jade kuro lara ọkunrin na. Nigbakugba ni isá ma mu u: a si fi ẹ̀wọn ati ṣẹkẹṣẹkẹ dè e; o si da gbogbo ìde na, ẹmi èṣu na si dari rẹ̀ si ijù.)

30. Jesu si bi i pe, Orukọ rẹ? o si dahùn pe, Legioni: nitoriti ẹmi eṣu pipọ wọ̀ ọ lara lọ.