6. O si gbà: o si nwá akoko ti o wọ̀, lati fi i le wọn lọwọ laìsi ariwo.
7. Ọjọ aiwukara pé, nigbati nwọn kò le ṣe aiṣẹbọ irekọja.
8. O si rán Peteru on Johanu, wipe, Ẹ lọ ipèse irekọja fun wa, ki awa ki o jẹ.
9. Nwọn si wi fun u pe, Nibo ni iwọ nfẹ ki a pèse sile?
10. O si wi fun wọn pe, Kiyesi i, nigbati ẹnyin ba nwọ̀ ilu lọ, ọkunrin kan ti o rù iṣa omi yio pade nyin; ẹ ba a lọ si ile ti o ba wọ̀.
11. Ki ẹ si wi fun bãle ile na pe, Olukọni wi fun ọ pe, Nibo ni gbọ̀ngan apejẹ na gbé wà, nibiti emi o gbé jẹ irekọja pẹlu awọn ọmọ-ẹhin mi?
12. On o si fi gbọ̀ngan nla kan loke hàn nyin, ti a ṣe lọṣọ: nibẹ̀ ni ki ẹnyin ki o pèse silẹ.
13. Nwọn si lọ nwọn si bá a gẹgẹ bi o ti sọ fun wọn: nwọn si pèse irekọja silẹ.
14. Nigbati akokò si to, o joko ati awọn aposteli pẹlu rẹ̀.
15. O si wi fun wọn pe, Tinu-tinu li emi fẹ fi ba nyin jẹ irekọja yi, ki emi ki o to jìya:
16. Nitori mo wi fun nyin, Emi kì yio jẹ ninu rẹ̀ mọ́, titi a o fi mú u ṣẹ ni ijọba Ọlọrun.
17. O si gbà ago, nigbati o si ti dupẹ, o wipe, Gbà eyi, ki ẹ si pín i larin ara nyin.