Yorùbá Bibeli

Luk 22:37-44 Yorùbá Bibeli (YCE)

37. Nitori mo wi fun nyin pe, Eyi ti a ti kọwe rẹ̀ kò le ṣe ki o má ṣẹ lara mi, A si kà a mọ awọn arufin. Nitori ohun wọnni nipa ti emi o li opin.

38. Nwọn si wipe, Oluwa, sawõ, idà meji mbẹ nihinyi. O si wi fun wọn pe, O to.

39. O si jade, o si lọ bi iṣe rẹ̀ si òke Olifi; awọn ọmọ-ẹhin rẹ̀ si tọ̀ ọ lẹhin.

40. Nigbati o wà nibẹ̀, o wi fun wọn pe, Ẹ mã gbadura, ki ẹnyin ki o máṣe bọ sinu idẹwò.

41. O si fi wọn silẹ niwọn isọko kan, o si kunlẹ o si ngbadura,

42. Wipe, Baba, bi iwọ ba fẹ, gbà ago yi lọwọ mi: ṣugbọn ifẹ ti emi kọ́, bikoṣe tirẹ ni ki a ṣe.

43. Angẹli kan si yọ si i lati ọrun wá, o ngbà a ni iyanju.

44. Bi o si ti wà ni iwaya-ija o ngbadura si i kikankikan: õgùn rẹ̀ si dabi iro ẹ̀jẹ nla, o nkán silẹ.