Yorùbá Bibeli

Luk 22:1-6 Yorùbá Bibeli (YCE)

1. AJỌ ọdun aiwukara ti a npè ni Irekọja si kù fẹfẹ.

2. Ati awọn olori alufa, ati awọn akọwe nwá ọ̀na bi nwọn iba ti ṣe pa a; nitoriti nwọn mbẹ̀ru awọn enia.

3. Satani si wọ̀ inu Judasi, ti a npè ni Iskariotu, ọkan ninu awọn mejila.

4. O si mu ọ̀na rẹ̀ pọ̀n, o lọ lati ba awọn olori alufa ati awọn olori ẹṣọ́ mọ̀ ọ pọ̀, bi on iba ti fi i le wọn lọwọ.

5. Nwọn si yọ̀, nwọn si ba a da majẹmu ati fun u li owo.

6. O si gbà: o si nwá akoko ti o wọ̀, lati fi i le wọn lọwọ laìsi ariwo.