Yorùbá Bibeli

Luk 20:35-47 Yorùbá Bibeli (YCE)

35. Ṣugbọn awọn ti a kà yẹ lati jogún aiye na, ati ajinde kuro ninu okú, nwọn kì igbeyawo, nwọn kì si ifà iyawo fun-ni:

36. Nitori nwọn kò le kú mọ́; nitoriti nwọn ba awọn angẹli dọgba; awọn ọmọ Ọlọrun si ni nwọn, nitori nwọn di awọn ọmọ ajinde.

37. Niti pe a njí awọn okú dide, Mose tikararẹ̀ si ti fihàn ni igbẹ́, nigbati o pè Oluwa ni Ọlọrun Abrahamu, ati Ọlọrun Isaaki, ati Ọlọrun Jakọbu.

38. Bẹni on kì iṣe Ọlọrun awọn okú, bikoṣe ti awọn alãye: nitori gbogbo wọn wà lãye fun u.

39. Nigbana li awọn kan ninu awọn akọwe da a lohùn, wipe, Olukọni iwọ wi rere.

40. Nwọn kò si jẹ bi i lẽre òrọ kan mọ́.

41. O si wi fun wọn pe, Ẽṣe ti nwọn fi nwipe, Ọmọ Dafidi ni Kristi?

42. Dafidi tikararẹ̀ si wi ninu iwe Psalmu pe, OLUWA wi fun Oluwa mi pe, Iwọ joko li ọwọ́ ọtún mi,

43. Titi emi o fi sọ awọn ọtá rẹ di apoti itisẹ rẹ.

44. Njẹ bi Dafidi ba pè e li Oluwa; on ha si ti ṣe jẹ ọmọ rẹ̀?

45. O si wi fun awọn ọmọ-ẹhin rẹ̀ li etí gbogbo enia pe,

46. Ẹ mã kiyesara lọdọ awọn akọwe, ti nwọn fẹ lati mã rìn li aṣọ gigùn, ti nwọn si fẹ ikí-ni li ọjà, ati ibujoko ọlá ninu sinagogu, ati ipò ọla ni ibi àse;

47. Awọn ti o jẹ ile awọn opó run, ti nwọn si ngbadura gìgun fun aṣehàn: awọn wọnyi na ni yio jẹbi pọ̀ju.