Yorùbá Bibeli

Luk 18:34-43 Yorùbá Bibeli (YCE)

34. Ọkan ninu nkan wọnyi kò si yé wọn: ọ̀rọ yi si pamọ́ fun wọn, bẹ̃ni nwọn ko si mọ̀ ohun ti a wi.

35. O si ṣe, bi on ti sunmọ Jeriko, afọju kan joko lẹba ọ̀na o nṣagbe:

36. Nigbati o gbọ́ ti ọpọ́ enia nkọja lọ, o bère pe, kili ã le mọ̀ eyi si.

37. Nwọn si wi fun u pe, Jesu ti Nasareti li o nkọja lọ.

38. O si kigbe pe, Jesu, iwọ Ọmọ Dafidi, ṣãnu fun mi.

39. Awọn ti nlọ niwaju ba a wi pe, ki o pa ẹnu rẹ̀ mọ́: ṣugbọn on si kigbe si i kunkun pe, Iwọ Ọmọ Dafidi, ṣãnu fun mi.

40. Jesu si dẹṣẹ duro, o ni, ki a mu u tọ̀ on wá: nigbati o si sunmọ ọ, o bi i,

41. Wipe, Kini iwọ nfẹ ti emi iba ṣe fun o? O si wipe, Oluwa, ki emi ki o le riran.

42. Jesu si wi fun u pe, Riran: igbagbọ́ rẹ gbà ọ là.

43. Lojukanna o si riran, o si ntọ̀ ọ lẹhin, o nyìn Ọlọrun logo: ati gbogbo enia nigbati nwọn ri i, nwọn fi iyìn fun Ọlọrun.