Yorùbá Bibeli

Luk 16:1-12 Yorùbá Bibeli (YCE)

1. O si wi fun awọn ọmọ-ẹhin rẹ̀ pẹlu pe, ọkunrin ọlọrọ̀ kan wà, ti o ni iriju kan; on na ni nwọn fi sùn u pe, o ti nfi ohun-ini rẹ̀ ṣòfo.

2. Nigbati o si pè e, o wi fun u pe, Ẽṣe ti emi fi ngbọ́ eyi si ọ? siro iṣẹ iriju rẹ; nitori iwọ ko le ṣe iriju mọ́.

3. Iriju na si wi ninu ara rẹ̀ pe, Ewo li emi o ṣe? nitoriti Oluwa mi gbà iṣẹ iriju lọwọ mi: emi kò le wàlẹ; lati ṣagbe oju ntì mi.

4. Mo mọ̀ eyiti emi o ṣe, nigbati a ba mu mi kuro nibi iṣẹ iriju, ki nwọn ki o le gbà mi sinu ile wọn.

5. O si pè awọn ajigbese oluwa rẹ̀ sọdọ rẹ̀, o si wi fun ekini pe, Elo ni iwọ jẹ oluwa mi?

6. O si wipe, Ọgọrun oṣuwọn oróro. O si wi fun u pe, Mu iwe rẹ, si joko nisisiyi, ki o si kọ adọta.

7. Nigbana li o si bi ẹnikeji pe, Elo ni iwọ jẹ? On si wipe, Ọgọrun oṣuwọn alikama. O si wi fun u pe, Mu iwe rẹ, ki o si kọ ọgọrin.

8. Oluwa rẹ̀ si yìn alaiṣõtọ iriju na, nitoriti o fi ọgbọ́n ṣe e: awọn ọmọ aiye yi sá gbọ́n ni iran wọn jù awọn ọmọ imọlẹ lọ.

9. Emi si wi fun nyin, ẹ fi mammoni aiṣõtọ yàn ọrẹ́ fun ara nyin pe, nigbati yio ba yẹ̀, ki nwọn ki o le gbà nyin si ibujoko wọn titi aiye.

10. Ẹniti o ba ṣe olõtọ li ohun kikini, o ṣe olõtọ ni pipọ pẹlu: ẹniti o ba si ṣe alaiṣõtọ li ohun kikini, o ṣe alaiṣõtọ li ohun pipo pẹlu.

11. Njẹ bi ẹnyin kò ba ti jẹ olõtọ ni mammoni aiṣõtọ, tani yio fi ọrọ̀ tõtọ ṣú nyin?

12. Bi ẹnyin ko ba si ti jẹ olõtọ li ohun ti iṣe ti ẹlomiran, tani yio fun nyin li ohun ti iṣe ti ẹnyin tikara nyin?