Yorùbá Bibeli

Luk 10:32-42 Yorùbá Bibeli (YCE)

32. Bẹ̃na si ni ọmọ Lefi kan pẹlu, nigbati o de ibẹ̀, ti o si ri i, o kọja lọ niha keji.

33. Ṣugbọn ara Samaria kan, bi o ti nrè àjo, o de ibi ti o gbé wà: nigbati o si ri i, ãnu ṣe e,

34. O si tọ̀ ọ lọ, o si dì i lọgbẹ, o da oróro on ọti-waini si i, o si gbé e le ori ẹranko ti on tikalarẹ̀, o si mu u wá si ile-èro, o si nṣe itọju rẹ̀.

35. Nigbati o si lọ ni ijọ keji, o fi owo idẹ meji fun olori ile-ero, o si wi fun u pe, Mã tọju rẹ̀; ohunkohun ti iwọ ba si ná kun u, nigbati mo ba pada de, emi ó san a fun ọ.

36. Ninu awọn mẹtẹta wọnyi, tani iwọ rò pe iṣe ẹnikeji ẹniti o bọ si ọwọ́ awọn ọlọṣà?

37. O si dahùn wipe, Ẹniti o ṣãnu fun u ni. Jesu si wi fun u pe, Lọ, ki iwọ ki o si ṣe bẹ̃ gẹgẹ.

38. O si ṣe, bi nwọn ti nlọ, o wọ̀ iletò kan: obinrin kan ti a npè ni Marta si gbà a si ile rẹ̀.

39. O si ni arabinrin kan ti a npè ni Maria, ti o si joko lẹba ẹsẹ Jesu, ti o ngbọ́ ọ̀rọ rẹ̀.

40. Ṣugbọn Marta nṣe iyọnu ohun pupọ, o si tọ̀ ọ wá, o ni, Oluwa, iwọ kò kuku ṣu si i ti arabinrin mi fi mi silẹ lati mã nikan ṣe aisimi? Wi fun u ki o ràn mi lọwọ.

41. Ṣugbọn Jesu si dahùn, o si wi fun u pe, Marta, Marta, iwọ nṣe aniyan ati lãlã nitori ohun pipọ:

42. Ṣugbọn ohun kan li a kò le ṣe alaini. Maria si ti yàn ipa rere na, ti a kò le gbà lọwọ rẹ̀.