Yorùbá Bibeli

Luk 1:67-79 Yorùbá Bibeli (YCE)

67. Sakariah baba rẹ̀ si kún fun Ẹmí Mimọ́, o si sọtẹlẹ, o ni,

68. Olubukun li Oluwa Ọlọrun Israeli; nitoriti o ti bojuwò, ti o si ti dá awọn enia rẹ̀ nide,

69. O si ti gbé iwo igbala soke fun wa ni ile Dafidi ọmọ-ọdọ rẹ̀;

70. Bi o ti wi li ẹnu awọn woli rẹ̀ mimọ́, ti nwọn ti mbẹ nigbati aiye ti ṣẹ̀:

71. Pe, a o gbà wa là lọwọ awọn ọtá wa, ati lọwọ gbogbo awọn ti o korira wa;

72. Lati ṣe ãnu ti o ti leri fun awọn baba wa, ati lati ranti majẹmu rẹ̀ mimọ́,

73. Ara ti o ti bú fun Abrahamu baba wa,

74. Pe on o fifun wa, lati gbà wa lọwọ awọn ọtá wa, ki awa ki o le ma sìn i laifòya,

75. Ni mimọ́ ìwa ati li ododo niwaju rẹ̀, li ọjọ aiye wa gbogbo.

76. Ati iwọ, ọmọ, woli Ọgá-ogo li a o ma pè ọ: nitori iwọ ni yio ṣaju Oluwa lati tún ọ̀na rẹ̀ ṣe;

77. Lati fi ìmọ igbala fun awọn enia rẹ̀ fun imukuro ẹ̀ṣẹ wọn,

78. Nitori iyọ́nu Ọlọrun wa; nipa eyiti ìla-õrùn lati oke wá bojuwò wa,

79. Lati fi imọlẹ fun awọn ti o joko li òkunkun ati li ojiji ikú, ati lati fi ẹsẹ wa le ọ̀na alafia.