Yorùbá Bibeli

Luk 1:48-60 Yorùbá Bibeli (YCE)

48. Nitoriti o ṣijuwò ìwa irẹlẹ ọmọbinrin ọdọ rẹ̀: sá wò o, lati isisiyi lọ gbogbo iran enia ni yio ma pè mi li alabukunfun.

49. Nitori ẹniti o li agbara ti ṣe ohun ti o tobi fun mi; mimọ́ si li orukọ rẹ̀.

50. Anu rẹ̀ si mbẹ fun awọn ti o bẹ̀ru rẹ̀ lati irandiran.

51. O ti fi agbara hàn li apa rẹ̀; o ti tú awọn onirera ká ni ironu ọkàn wọn.

52. O ti mu awọn alagbara kuro lori itẹ́ wọn, o si gbé awọn talakà leke.

53. O ti fi ohun ti o dara kún awọn ti ebi npa; o si rán awọn ọlọrọ̀ pada lọwọ ofo.

54. O ti ràn Israeli ọmọ-ọdọ rẹ̀ lọwọ, ni iranti ãnu rẹ̀;

55. Bi o ti sọ fun awọn baba wa, fun Abrahamu, ati fun irú-ọmọ rẹ̀ lailai.

56. Maria si ba a joko niwọn oṣù mẹta, o si pada lọ si ile rẹ̀.

57. Ọjọ Elisabeti pe wayi ti yio bí; o si bí ọmọkunrin kan.

58. Ati awọn aladugbo, ati awọn ibatan rẹ̀ gbọ́ bi Oluwa ti ṣe ãnu nla fun u; nwọn si ba a yọ̀.

59. O si ṣe, ni ijọ kẹjọ nwọn wá lati kọ ọmọ na nila; nwọn si sọ orukọ rẹ̀ ni Sakariah, gẹgẹ bi orukọ baba rẹ̀.

60. Iya rẹ̀ si dahùn, o ni Bẹ̃kọ; bikoṣe Johanu li a o pè e.