Ki ẹnyin ki o si kede li ọjọ́ na gan; ki o le jẹ́ apejọ mimọ́ fun nyin: ẹnyin kò gbọdọ ṣe iṣẹ agbara kan: yio si ma ṣe ìlana fun nyin titilai ni ibujoko nyin gbogbo ni iran-iran nyin.