Yorùbá Bibeli

Lef 1:1-11 Yorùbá Bibeli (YCE)

1. OLUWA si pè Mose, o si sọ fun u lati inu agọ́ ajọ wa, pe,

2. Sọ fun awọn ọmọ Israeli, ki o si wi fun wọn pe, Bi ẹnikan ninu nyin ba mú ọrẹ-ẹbọ wá fun OLUWA, ki ẹnyin ki o mú ọrẹ-ẹbọ nyin wá ninu ohunọ̀sin, ani ti inu ọwọ́-ẹran, ati ti agbo-ẹran.

3. Bi ọrẹ-ẹbọ rẹ̀ ba ṣe ẹbọ sisun ti inu ọwọ́-ẹran, ki on ki o mú akọ wá alailabùku: ki o mú u wá tinutinu rẹ̀ si ẹnu-ọ̀na agọ́ ajọ siwaju OLUWA.

4. Ki o si fi ọwọ rẹ̀ lé ori ẹbọ sisun na; yio si di itẹwọgbà fun u lati ṣètutu fun u.

5. Ki o si pa akọmalu na niwaju OLUWA: awọn alufa, awọn ọmọ Aaroni, yio si mú ẹ̀jẹ na wá, nwọn o si fi ẹ̀jẹ na wọ́n ori pẹpẹ nì yiká ti mbẹ li ẹnu-ọ̀na agọ́ ajọ.

6. Ki o si bó ẹbọ sisun na; ki o si kun u.

7. Awọn ọmọ Aaroni alufa ni yio si fi iná sori pẹpẹ na, nwọn o si tò igi lori iná na:

8. Awọn alufa, awọn ọmọ Aaroni yio si tò ninu rẹ̀, ani ori ati ọrá wọn sori igi ti mbẹ lori iná, ti mbẹ lori pẹpẹ:

9. Ṣugbọn ifun rẹ̀, ati itan rẹ̀ ni ki o ṣàn ninu omi: ki alufa ki o si sun gbogbo rẹ̀ lori pẹpẹ na lati ṣe ẹbọ sisun, ẹbọ ti a fi iná ṣe, õrùn didùn si OLUWA.

10. Bi ọrẹ-ẹbọ rẹ̀ ba si ṣe ti agbo-ẹran, eyinì ni ti agutan, tabi ti ewurẹ, fun ẹbọ sisun; akọ ni ki o múwa alailabùku.

11. Ki o si pa a niwaju OLUWA li ẹba pẹpẹ ni ìha ariwa: ati awọn alufa, awọn ọmọ Aaroni yio si bù ẹ̀jẹ rẹ̀ wọ́n ori pẹpẹ na yiká.