32. Lati igba ti aiye ti ṣẹ̀, a kò ti igbọ́ pe, ẹnikan là oju ẹniti a bí li afọju rí.
33. Ibaṣepe ọkunrin yi ko ti ọdọ Ọlọrun wá, kì ba ti le ṣe ohunkohun.
34. Nwọn si dahùn wi fun u pe, Ninu ẹṣẹ li a bi iwọ patapata, iwọ si nkọ́ wa bi? Nwọn si tì i sode.
35. Jesu gbọ́ pe, nwọn ti tì i sode; nigbati o si ri i, o wipe, Iwọ gbà Ọmọ Ọlọrun gbọ́ bi?
36. On si dahùn wipe, Tani, Oluwa, ki emi ki o le gbà a gbọ́?