45. Ṣugbọn nitori emi sọ otitọ fun nyin, ẹ kò si gbà mi gbọ́.
46. Tani ninu nyin ti o ti idá mi li ẹbi ẹ̀ṣẹ? Bi mo ba nsọ otitọ ẽṣe ti ẹnyin kò fi gbà mi gbọ́?
47. Ẹniti iṣe ti Ọlọrun, a ma gbọ́ ọ̀rọ Ọlọrun: nitori eyi li ẹnyin kò ṣe gbọ, nitori ẹnyin kì iṣe ti Ọlọrun.
48. Awọn Ju dahùn nwọn si wi fun u pe, Awa kò wi nitõtọ pe, ara Samaria ni iwọ iṣe, ati pe iwọ li ẹmi èṣu?
49. Jesu dahùn wipe, Emi kò li ẹmi èṣu; ṣugbọn emi mbọlá fun Baba mi, ẹnyin kò si bọla fun mi.
50. Emi kò wá ogo ara mi: ẹnikan mbẹ ti o nwà a ti o si nṣe idajọ.
51. Lõtọ, lõtọ ni mo wi fun nyin, Bi ẹnikan ba pa ọ̀rọ mi mọ́, ki yio ri ikú lailai.
52. Awọn Ju wi fun u pe, Nigbayi ni awa mọ̀ pe iwọ li ẹmi èṣu. Abrahamu kú, ati awọn woli; iwọ si wipe, Bi ẹnikan ba pa ọ̀rọ mi mọ́, kì yio tọ́ ikú wò lailai.
53. Iwọ ha pọ̀ju Abrahamu baba wa lọ, ẹniti o kú? awọn woli si kú: tani iwọ nfi ara rẹ pè?
54. Jesu dahùn wipe, Bi mo ba nyìn ara mi li ogo, ogo mi kò jẹ nkan: Baba mi ni ẹniti nyìn mi li ogo, ẹniti ẹnyin wipe, Ọlọrun nyin ni iṣe:
55. Ẹ kò si mọ̀ ọ; ṣugbọn emi mọ̀ ọ: bi mo ba si wipe, emi kò mọ̀ ọ, emi ó di eke gẹgẹ bi ẹnyin: ṣugbọn emi mọ̀ ọ, mo si pa ọ̀rọ rẹ̀ mọ́.
56. Abrahamu baba nyin yọ̀ lati ri ọjọ mi: o si ri i, o si yọ̀.
57. Nitorina awọn Ju wi fun u pe, Ọdún rẹ kò ti ito adọta, iwọ si ti ri Abrahamu?