Yorùbá Bibeli

Joh 6:15-29 Yorùbá Bibeli (YCE)

15. Nigbati Jesu si woye pe, nwọn nfẹ wá ifi agbara mu on lọ ifi jọba, o tún pada lọ sori òke on nikan.

16. Nigbati alẹ si lẹ, awọn ọmọ-ẹhin rẹ̀ lọ sinu okun.

17. Nwọn si bọ sinu ọkọ̀, nwọn si rekọja okun lọ si Kapernaumu. Okunkun si ti kùn, Jesu kò si ti ide ọdọ wọn.

18. Okun si nru nitori ẹfufu lile ti nfẹ.

19. Nigbati nwọn wà ọkọ̀ to bi ìwọn furlongi mẹdọgbọn tabi ọgbọ̀n, nwọn ri Jesu nrìn lori okun, o si sunmọ ọkọ̀; ẹ̀ru si bà wọn.

20. Ṣugbọn o wi fun wọn pe, Emi ni; ẹ má bẹ̀ru.

21. Nitorina nwọn fi ayọ̀ gbà a sinu ọkọ̀: lojukanna ọkọ̀ na si de ilẹ ibiti nwọn gbé nlọ.

22. Ni ijọ keji, nigbati awọn enia ti o duro li apakeji okun ri pe, kò si ọkọ̀ miran nibẹ̀, bikoṣe ọkanna ti awọn ọmọ-ẹhin rẹ̀ wọ̀, ati pe Jesu kò ba awọn ọmọ-ẹhin rẹ̀ wọ̀ inu ọkọ̀ na, ṣugbọn awọn ọmọ-ẹhin rẹ̀ nikan li o lọ;

23. (Ṣugbọn awọn ọkọ̀ miran ti Tiberia wá, leti ibi ti nwọn gbe jẹ akara, lẹhin igbati Oluwa ti dupẹ:)

24. Nitorina nigbati awọn enia ri pe, Jesu kò si nibẹ̀, tabi awọn ọmọ-ẹhin rẹ̀, awọn pẹlu wọ̀ ọkọ̀ lọ si Kapernaumu, nwọn nwá Jesu.

25. Nigbati nwọn si ri i li apakeji okun nwọn wi fun u pe, Rabbi, nigbawo ni iwọ wá sihinyi?

26. Jesu da wọn lohùn o si wipe, Lõtọ, lõtọ ni mo wi fun nyin, Ẹnyin nwá mi, ki iṣe nitoriti ẹnyin ri iṣẹ àmi, ṣugbọn nitori ẹnyin jẹ iṣu akara wọnni, ẹnyin si yó.

27. Ẹ máṣe ṣiṣẹ fun onjẹ ti iṣegbé, ṣugbọn fun onjẹ ti iwà ti di ìye ainipẹkun, eyiti Ọmọ-enia yio fifun nyin: nitoripe on ni, ani Ọlọrun Baba ti fi edidi dí.

28. Nigbana ni nwọn wi fun u pe, Kili awa o ha ṣe, ki a le ṣe iṣẹ Ọlọrun?

29. Jesu dahùn o si wi fun wọn pe, Eyi ni iṣẹ Ọlọrun pe, ki ẹnyin ki o gbà ẹniti o rán gbọ́.