Yorùbá Bibeli

Joh 6:1-9 Yorùbá Bibeli (YCE)

1. LẸHIN nkan wọnyi, Jesu kọja si apakeji okun Galili, ti iṣe okun Tiberia.

2. Ọpọ ijọ enia si tọ̀ ọ lẹhin, nitoriti nwọn ri iṣẹ àmi rẹ̀, ti o nṣe lara awọn alaisàn.

3. Jesu si gùn ori òke lọ, nibẹ̀ li o si gbé joko pẹlu awọn ọmọ-ẹhin rẹ̀.

4. Ajọ irekọja, ọdun awọn Ju, si sunmọ etile.

5. Njẹ bi Jesu ti gbé oju rẹ̀ soke, ti o si ri ọ̀pọ enia wá sọdọ rẹ̀, o wi fun Filippi pe, Nibo li a o ti rà akara, ki awọn wọnyi le jẹ?

6. O si sọ eyi lati dán a wò; nitoriti on tikararẹ̀ mọ̀ ohun ti on ó ṣe.

7. Filippi da a lohùn pe, Akara igba owo idẹ ko to fun wọn, ti olukuluku wọn iba fi mu diẹ-diẹ.

8. Ọkan ninu awọn ọmọ-ẹhin rẹ̀, Anderu, arakunrin Simoni Peteru wi fun u pe,

9. Ọmọdekunrin kan mbẹ nihinyi, ti o ni iṣu akara barle marun, ati ẹja kékèké meji: ṣugbọn kini wọnyi jẹ lãrin ọ̀pọ enia wọnyi bi eyi?