Yorùbá Bibeli

Joh 16:1-10 Yorùbá Bibeli (YCE)

1. NKAN wọnyi ni mo ti sọ fun nyin, ki a má ba mu nyin kọsẹ̀.

2. Nwọn o yọ nyin kuro ninu sinagogu: ani, akokò mbọ̀, ti ẹnikẹni ti o ba pa nyin, yio rò pe on nṣe ìsin fun Ọlọrun.

3. Nkan wọnyi ni nwọn o si ṣe, nitoriti nwọn kò mọ̀ Baba, nwọn kò si mọ̀ mi.

4. Ṣugbọn nkan wọnyi ni mo ti sọ fun nyin, pe nigbati wakati wọn ba de, ki ẹ le ranti wọn pe mo ti wi fun nyin. Ṣugbọn emi ko sọ nkan wọnyi fun nyin lati ipilẹṣẹ wá, nitoriti mo wà pẹlu nyin.

5. Ṣugbọn nisisiyi emi nlọ sọdọ ẹniti o rán mi; kò si si ẹnikan ninu nyin ti o bi mi lẽre pe, Nibo ni iwọ nlọ?

6. Ṣugbọn nitori mo sọ nkan wọnyi fun nyin, ibinujẹ kún ọkàn nyin.

7. Ṣugbọn otitọ li emi nsọ fun nyin; Anfani ni yio jẹ fun nyin bi emi ba lọ: nitori bi emi kò ba lọ, Olutunu kì yio tọ̀ nyin wá: ṣugbọn bi mo ba lọ, emi o rán a si nyin.

8. Nigbati on ba si de, yio fi òye yé araiye niti ẹ̀ṣẹ, ati niti ododo, ati niti idajọ:

9. Niti ẹ̀ṣẹ, nitoriti nwọn kò gbà mi gbọ́;

10. Niti ododo, nitoriti emi nlọ sọdọ Baba, ẹnyin kò si ri mi mọ́;