Yorùbá Bibeli

Joh 10:39-42 Yorùbá Bibeli (YCE)

39. Nwọn si tun nwá ọ̀na lati mu u: o si bọ́ lọwọ wọn.

40. O si tún kọja lọ si apakeji Jordani si ibiti Johanu ti kọ́ mbaptisi; nibẹ̀ li o si joko.

41. Awọn enia pipọ si wá sọdọ rẹ̀, nwọn si wipe, Johanu ko ṣe iṣẹ àmi kan: ṣugbọn otitọ li ohun gbogbo ti Johanu sọ nipa ti ọkunrin yi.

42. Awọn enia pipọ nibẹ̀ si gbà a gbọ́.