Yorùbá Bibeli

Joh 10:15-26 Yorùbá Bibeli (YCE)

15. Gẹgẹ bi Baba ti mọ̀ mi, ti emi si mọ̀ Baba; mo si fi ẹmí mi lelẹ nitori awọn agutan.

16. Emi si ní awọn agutan miran, ti kì iṣe ti agbo yi: awọn li emi kò le ṣe alaimu wá pẹlu, nwọn ó si gbọ ohùn mi; nwọn o si jẹ agbo kan, oluṣọ-agutan kan.

17. Nitorina ni Baba mi ṣe fẹran mi, nitoriti mo fi ẹmí mi lelẹ, ki emi ki o le tún gbà a.

18. Ẹnikan kò gbà a lọwọ mi, ṣugbọn mo fi i lelẹ fun ara mi. Mo li agbara lati fi i lelẹ, mo si li agbara lati tún gbà a. Aṣẹ yi ni mo ti gbà lati ọdọ Baba mi wá.

19. Nitorina iyapa tun wà larin awọn Ju nitori ọ̀rọ wọnyi.

20. Ọpọ ninu wọn si wipe, O li ẹmi èṣu, ori rẹ̀ si bajẹ; ẽṣe ti ẹnyin ngbọ̀rọ rẹ̀?

21. Awọn miran wipe, Wọnyi kì iṣe ọ̀rọ ẹniti o li ẹmi èsu. Ẹmi èsu le là oju awọn afọju bi?

22. O si jẹ ajọ ọdun iyasimimọ́ ni Jerusalemu, igba otutù ni.

23. Jesu si nrìn ni tẹmpili, nì ìloro Solomoni.

24. Nitorina awọn Ju wá duro yi i ká, nwọn si wi fun u pe, Iwọ ó ti mu wa ṣe iyemeji pẹ to? Bi iwọ ni iṣe Kristi na, wi fun wa gbangba.

25. Jesu da wọn lohùn wipe, Emi ti wi fun nyin, ẹnyin kò si gbagbọ́; iṣẹ ti emi nṣe li orukọ Baba mi, awọn ni njẹri mi.

26. Ṣugbọn ẹnyin kò gbagbọ́, nitori ẹnyin kò si ninu awọn agutan mi, gẹgẹ bi mo ti wi fun nyin.