Yorùbá Bibeli

Joṣ 3:1-10 Yorùbá Bibeli (YCE)

1. JOṢUA si dide ni kùtukutu owurọ̀, nwọn si ṣí kuro ni Ṣittimu, nwọn si dé Jordani, on ati gbogbo awọn ọmọ Israeli; nwọn si sùn sibẹ̀ ki nwọn ki o to gòke odò.

2. O si ṣe lẹhin ijọ́ mẹta, ni awọn olori là ãrin ibudó já;

3. Nwọn si paṣẹ fun awọn enia, wipe, Nigbati ẹnyin ba ri apoti majẹmu OLUWA Ọlọrun nyin, ti ẹ ba si ri awọn alufa awọn ọmọ Lefi rù u, nigbana li ẹnyin o ṣí kuro ni ipò nyin, ẹnyin o si ma tọ̀ ọ lẹhin.

4. Ṣugbọn alafo yio wà li agbedemeji ti ẹnyin tirẹ̀, to bi ìwọn ẹgba igbọnwọ: ẹ má ṣe sunmọ ọ, ki ẹnyin ki o le mọ̀ ọ̀na ti ẹnyin o gbà; nitoriti ẹnyin kò gbà ọ̀na yi rí.

5. Joṣua si wi fun awọn enia pe, Ẹ yà ara nyin simimọ́: nitori li ọla OLUWA yio ṣe ohuniyanu lãrin nyin.

6. Joṣua si wi fun awọn alufa pe, Ẹ gbé apoti majẹmu na, ki ẹ si kọja siwaju awọn enia. Nwọn si gbé apoti majẹmu na, nwọn si ṣaju awọn enia.

7. OLUWA si wi fun Joṣua pe, Li oni yi li emi o bẹ̀rẹsi gbé ọ ga li oju gbogbo Israeli, ki nwọn ki o le mọ̀ pe, gẹgẹ bi mo ti wà pẹlu Mose, bẹ̃li emi o wà pẹlu rẹ.

8. Iwọ o si paṣẹ fun awọn alufa ti o rù apoti majẹmu na pe, Nigbati ẹnyin ba dé eti odò Jordani, ki ẹnyin ki o duro jẹ ni Jordani.

9. Joṣua si wi fun awọn ọmọ Israeli pe, Ẹ sunmọ ihin, ki ẹ si gbọ́ ọ̀rọ OLUWA Ọlọrun nyin.

10. Joṣua si wipe, Nipa eyi li ẹnyin o mọ̀ pe Ọlọrun alãye mbẹ lãrin nyin, ati pe dajudaju on o lé awọn ara Kenaani, ati awọn Hitti, ati awọn Hifi, ati awọn Perissi, ati awọn Girgaṣi ati awọn Amori, ati awọn Jebusi, kuro niwaju nyin.