Yorùbá Bibeli

Joṣ 23:14-16 Yorùbá Bibeli (YCE)

14. Ẹnyin kiyesi i, li oni emi nlọ si ọ̀na gbogbo aiye: ényin si mọ̀ li àiya nyin gbogbo, ati li ọkàn nyin gbogbo pe, kò sí ohun kan ti o tase ninu ohun rere gbogbo ti OLUWA Ọlọrun nyin ti sọ niti nyin; gbogbo rẹ̀ li o ṣẹ fun nyin, kò si sí ohun ti o tase ninu rẹ̀.

15. Yio si ṣe, gẹgẹ bi ohun rere gbogbo ti ṣẹ fun nyin, ti OLUWA Ọlọrun nyin ti sọ fun nyin; bẹ̃ni OLUWA yio mú ibi gbogbo bá nyin, titi yio fi pa nyin run kuro ni ilẹ daradara yi ti OLUWA Ọlọrun nyin ti fi fun nyin.

16. Nigbati ẹnyin ba re majẹmu OLUWA Ọlọrun nyin kọja, ti o palaṣẹ fun nyin, ti ẹ ba si lọ, ti ẹ ba nsìn oriṣa ti ẹnyin ba tẹ̀ ori nyin bà fun wọn; nigbana ni ibinu OLUWA yio rú si nyin, ẹnyin o si ṣegbé kánkan kuro ni ilẹ daradara ti o ti fi fun nyin.