Yorùbá Bibeli

Joṣ 21:15-21 Yorùbá Bibeli (YCE)

15. Ati Holoni pẹlu àgbegbe rẹ̀, ati Debiri pẹlu àgbegbe rẹ̀;

16. Ati Aini pẹlu àgbegbe rẹ̀, ati Jutta pẹlu àgbegbe rẹ̀, ati Beti-ṣemeṣi pẹlu àgbegbe rẹ̀; ilu mẹsan ninu awọn ẹ̀ya meji wọnni.

17. Ati lati inu ẹ̀ya Benjamini, Gibeoni pẹlu àgbegbe rẹ̀, Geba pẹlu àgbegbe rẹ̀;

18. Anatotu pẹlu àgbegbe rẹ̀, ati Almoni pelu àgbegbe rẹ̀; ilu mẹrin.

19. Gbogbo ilu awọn ọmọ Aaroni, awọn alufa, jẹ́ ilu mẹtala pẹlu àgbegbe wọn.

20. Ati idile awọn ọmọ Kohati, awọn ọmọ Lefi, ani awọn ọmọ Kohati ti o kù, nwọn ní ilu ti iṣe ipín ti wọn lati inu ẹ̀ya Efraimu.

21. Nwọn si fi Ṣekemu fun wọn pẹlu àgbegbe rẹ̀, ni ilẹ òke Efraimu, ilu àbo fun apania, ati Geseri pẹlu àgbegbe rẹ̀;