Yorùbá Bibeli

Joṣ 19:31-49 Yorùbá Bibeli (YCE)

31. Eyi ni ilẹ-iní ẹ̀ya awọn ọmọ Aṣeri gẹgẹ bi idile wọn, ilu wọnyi pẹlu ileto wọn.

32. Ipín kẹfa yọ fun awọn ọmọ Naftali, ani fun awọn ọmọ Naftali gẹgẹ bi idile wọn.

33. Àla wọn si bẹ̀rẹ lati Helefu, lati igi-oaku Saanannimu, ati Adami-nekebu, ati Jabneeli dé Lakkumu; o si yọ si Jordani.

34. Àla na si ṣẹri lọ sí ìha ìwọ-õrùn si Asnoti-taboru, o si ti ibẹ̀ lọ si Hukkoki; o si dé Sebuluni ni gusù, o si dé Aṣeri ni ìwọ-õrùn, ati Juda ni Jordani ni ìha ìla-õrùn.

35. Awọn ilu olodi si ni Siddimu, Seri, ati Hammati, Rakkati, ati Kinnereti;

36. Ati Adama, ati Rama, ati Hasoru;

37. Ati Kedeṣi, ati Edrei, ati Eni-hasoru;

38. Ati Ironi, ati Migdali-eli, Horemu, ati Beti-anati, ati Beti-ṣemeṣi; ilu mọkandilogun pẹlu ileto wọn.

39. Eyi ni ilẹ-iní ẹ̀ya awọn ọmọ Naftali gẹgẹ bi idile wọn, ilu wọnyi pẹlu ileto wọn.

40. Ilẹ keje yọ fun ẹ̀ya awọn ọmọ Dani gẹgẹ bi idile wọn.

41. Àla ilẹ-iní wọn si ni Sora, ati Eṣtaolu, ati Iri-ṣemeṣi;

42. Ati Ṣaalabbini, ati Aijaloni, ati Itla;

43. Ati Eloni, ati Timna, ati Ekroni;

44. Ati Elteke, ati Gibbetoni, ati Baalati;

45. Ati Jehudi, ati Bene-beraki, ati Gati-rimmọni;

46. Ati Me-jarkoni, ati Rakkoni, pẹlu àla ti mbẹ kọjusi Jọppa.

47. Awọn ọmọ Dani si gbọ̀n àla wọn lọ: awọn ọmọ Dani si gòke lọ ibá Leṣemu jà, nwọn si kó o, nwọn si fi oju idà kọlù u, nwọn si gbà a, nwọn si ngbé inu rẹ̀, nwọn si pè Leṣemu ni Dani, gẹgẹ bi orukọ Dani baba wọn.

48. Eyi ni ilẹ-iní ẹ̀ya ọmọ Dani gẹgẹ bi idile wọn, ilu wọnyi pẹlu ileto wọn.

49. Nwọn si pari pipín ilẹ na fun ilẹ-iní gẹgẹ bi àla rẹ̀; awọn ọmọ Israeli si fi ilẹ-iní kan fun Joṣua ọmọ Nuni lãrin wọn: