Yorùbá Bibeli

Joṣ 18:14-28 Yorùbá Bibeli (YCE)

14. A si fà àla na lọ, o si yi si ìha ìwọ-õrùn lọ si gusù, lati òke ti mbẹ niwaju Beti-horoni ni ìha gusù; o si yọ si Kiriati-baali (ti ṣe Kiriati-jearimu), ilu awọn ọmọ Juda kan: eyi ni apa ìwọ-õrùn.

15. Ati apa gusù ni lati ipẹkun Kiriati-jearimu, àla na si yọ ìwọ-õrùn, o si yọ si isun omi Neftoa:

16. Àla na si sọkalẹ lọ si ipẹkun òke ti mbẹ niwaju afonifoji ọmọ Hinnomu, ti o si mbẹ ni afonifoji Refaimu ni ìha ariwa; o si sọkalẹ lọ si afonifoji Hinnomu, si apa Jebusi ni ìha gusù, o si sọkalẹ lọ si Eni-rogeli;

17. A si fà a lati ariwa lọ, o si yọ si Eni-ṣemeṣi, o si yọ si Gelilotu, ti o kọjusi òke Adummimu; o si sọkalẹ lọ si okuta Bohani ọmọ Reubeni;

18. O si kọja lọ si apa ibi ti o kọjusi Araba ni ìha ariwa, o si sọkalẹ lọ si Araba:

19. Àla na si kọja lọ dé apa Beti-hogla ni ìha ariwa: àla na si yọ ni ìha ariwa si kọ̀rọ Okun Iyọ̀, ni ipẹkun gusù ti Jordani: eyi ni àla gusù.

20. Jordani si ni àla rẹ̀ ni ìha ìla-õrùn. Eyi ni ilẹ-iní awọn ọmọ Benjamini, li àgbegbe rẹ̀ kakiri, gẹgẹ bi idile wọn.

21. Njẹ ilu ẹ̀ya awọn ọmọ Benjamini gẹgẹ bi idile wọn, ni Jeriko, ati Beti-hogla, ati Emekikesisi;

22. Ati Beti-araba, ati Semaraimu, ati Beti-eli;

23. Ati Affimu, ati Para, ati Ofra;

24. Ati Kefari-ammoni, ati Ofni, ati Geba; ilu mejila pẹlu ileto wọn:

25. Gibeoni, ati Rama, ati Beerotu;

26. Ati Mispe, ati Kefira, ati Mosa;

27. Ati Rekemu, ati Irpeeli, ati Tarala;

28. Ati Sela, Elefu, ati Jebusi (ti iṣe Jerusalemu), Gibeati, ati Kitiria; ilu mẹrinla pẹlu ileto wọn. Eyi ni ilẹ-iní awọn ọmọ Benjamini gẹgẹ bi idile wọn.