Yorùbá Bibeli

2. Kor 9:5-11 Yorùbá Bibeli (YCE)

5. Nitorina ni mo ṣe rò pe o yẹ lati gbà awọn arakunrin niyanju, ki nwọn ki o ṣaju tọ̀ nyin wá, ki nwọn ki o si mura ẹ̀bun nyin silẹ, ti ẹ ti ṣe ileri tẹlẹ ki a le ṣe eyi na silẹ, ki o le jasi bi ohun ẹ̀bun, ki o má si ṣe dabi ti ojukòkoro.

6. Ṣugbọn eyi ni mo wipe, Ẹniti o ba funrugbin kiun, kiun ni yio ká; ẹniti o ba si funrugbin, pupọ, pupọ ni yio ká.

7. Ki olululuku enia ki o ṣe gẹgẹ bi o ti pinnu li ọkàn rẹ̀; kì iṣe àfẹ̀kùnṣe, tabi ti alaigbọdọ má ṣe: nitori Ọlọrun fẹ oninudidun ọlọrẹ.

8. Ọlọrun si le mu ki gbogbo ore-ọfẹ ma bisi i fun nyin; ki ẹnyin, ti o ni anito ohun gbogbo nigbagbogbo, le mã pọ̀ si i ni iṣẹ́ rere gbogbo:

9. (Gẹgẹ bi a ti kọ ọ pe, O ti fọnka; o ti fifun awọn talakà: ododo rẹ̀ duro lailai.

10. Njẹ ẹniti nfi irugbin fun afunrugbin, ati akara fun onjẹ, yio fi irugbin fun nyin, yio si sọ ọ di pipọ fun irugbin, yio si mu eso ododo nyin bi si i.)

11. Ẹnyin ti a ti sọ di ọlọrọ̀ ninu ohun gbogbo, fun ilawọ gbogbo ti nṣiṣẹ ọpẹ si Ọlọrun nipa wa.