Yorùbá Bibeli

2. Kor 10:9-18 Yorùbá Bibeli (YCE)

9. Ki o máṣe dabi ẹnipe emi o fi iwe-kikọ dẹruba nyin.

10. Nitori nwọn wipe, iwe rẹ̀ wuwo, nwọn si lagbara; ṣugbọn ìrísi rẹ̀ jẹ alailera, ọ̀rọ rẹ̀ kò nilari.

11. Ki irú enia bẹ̃ ki o ro bayi pe, irú ẹniti awa iṣe li ọ̀rọ nipa iwe-kikọ nigbati awa kò si, irú bẹ̃li awa o si jẹ ni iṣe pẹlu nigbati awa ba wà.

12. Nitoripe awa kò daṣa ati kà ara wa mọ́, tabi ati fi ara wa wé awọn miran ninu wọn ti ńyìn ara wọn; ṣugbọn awọn tikarawọn jẹ alailoye nigbati nwọn nfi ara wọn diwọn ara wọn, ti nwọn si nfi ara wọn wé ara wọn.

13. Ṣugbọn awa kò ṣogo rekọja ãlà wa, ṣugbọn nipa ãlà ti Ọlọrun ti pín fun wa, ani ãlà kan lati de ọdọ nyin.

14. Nitori awa kò nawọ́ wa rekọja rara, bi ẹnipe awa kò de ọdọ nyin: nitori awa tilẹ de ọdọ nyin pẹlu ninu ihinrere Kristi.

15. Awa kò ṣogo rekọja ãlà wa, eyini ni lori iṣẹ ẹlomiran; ṣugbọn awa ni ireti pe, bi igbagbọ nyin ti ndagba si i, gẹgẹ bi àla wa awa o di gbigbega lọdọ nyin si i lọpọlọpọ,

16. Ki a ba le wasu ihinrere ani ni ẹkùn ti mbẹ niwaju nyin, ki a má si ṣogo ninu ãlà ẹlomiran nipa ohun ti o wà li arọwọto.

17. Ṣugbọn ẹniti o ba nṣogo, ki o mã ṣogo ninu Oluwa.

18. Nitoripe kì iṣe ẹniti nyìn ara rẹ̀ li o yanju, bikoṣe ẹniti Oluwa yìn.