Yorùbá Bibeli

2. Kor 10:4-9 Yorùbá Bibeli (YCE)

4. (Nitori ohun ija wa kì iṣe ti ara, ṣugbọn o li agbara ninu Ọlọrun lati wó ibi giga palẹ;)

5. Awa nsọ gbogbo ero kalẹ, ati gbogbo ohun giga ti ngbé ara rẹ̀ ga si ìmọ Ọlọrun, awa si ndi gbogbo ero ni igbekun wá si itẹriba fun Kristi;

6. Awa si ti mura tan lati gbẹsan gbogbo aigbọran, nigbati igbọran nyin ba pé.

7. Ẹnyin si nwò nkan gẹgẹ bi nwọn ti fi ara hàn lode. Bi ẹnikẹni ba gbẹkẹle ara rẹ̀ pe, ti Kristi li on iṣe, ẹ jẹ ki on ki o si tún rò eyi ninu ara rẹ̀ pe, bi on ti jẹ́ ti Kristi, gẹgẹ bẹ̃li awa pẹlu si jẹ́ ti Kristi.

8. Nitori bi mo tilẹ nṣogo aṣerekọja nitori aṣẹ wa, ti Oluwa ti fifun wa fun idagbasoke nyin ki iṣe fun ìbiṣubu nyin, oju ki yio tì mi;

9. Ki o máṣe dabi ẹnipe emi o fi iwe-kikọ dẹruba nyin.