Yorùbá Bibeli

2. A. Ọba 22:8-16 Yorùbá Bibeli (YCE)

8. Hilkiah olori alufa si sọ fun Ṣafani akọwe pe, Emi ri iwe ofin ni ile Oluwa. Hilkiah si fi iwe na fun Ṣafani, on si kà a.

9. Ṣafani akọwe si wá sọdọ ọba, o si tún mu èsi pada fun ọba wá, o si wipe, Awọn iranṣẹ rẹ ti kó owo na jọ ti a ri ni ile na, nwọn si ti fi le ọwọ awọn ti o nṣiṣẹ na, ti nṣe alabojuto ile Oluwa.

10. Ṣafani akọwe si fi hàn ọba, pe, Hilkiah alufa fi iwe kan le mi lọwọ. Ṣafani si kà a niwaju ọba.

11. O si ṣe, nigbati ọba gbọ́ ọ̀rọ inu iwe ofin na, o si fà aṣọ rẹ̀ ya.

12. Ọba si paṣẹ fun Hilkiah alufa, ati Ahikamu ọmọ Ṣafani, ati Akbori ọmọ Mikaiah, ati Ṣafani akọwe, ati Asahiah iranṣẹ ọba wipe,

13. Ẹ lọ, ẹ bère lọwọ Oluwa fun mi, ati fun awọn enia, ati fun gbogbo Juda, niti ọ̀rọ iwe yi ti a ri: nitori titobi ni ibinu Oluwa ti o rú si wa, nitori awọn baba wa kò fi eti si ọ̀rọ iwe yi, lati ṣe gẹgẹ bi gbogbo eyiti a kọwe silẹ fun wa.

14. Bẹ̃ni Hilkiah alufa, ati Ahikamu, ati Akbori, ati Ṣafani, ati Asahiah tọ̀ Hulda woli obinrin lọ, aya Ṣallumu, ọmọ Tikfa, ọmọ Harhasi, alabojuto aṣọ (njẹ on ngbe Jerusalemu niha keji); nwọn si ba a sọ̀rọ.

15. On si wi fun wọn pe, Bayi li Oluwa Ọlọrun Israeli wi, Sọ fun ọkunrin ti o rán nyin si mi pe,

16. Bayi li Oluwa wi, Kiyesi i, emi o mu ibi bá ibiyi, ati bá awọn ara ilu na, ani gbogbo ọ̀rọ iwe na ti ọba Juda ti kà.