Yorùbá Bibeli

2. A. Ọba 22:1-9 Yorùbá Bibeli (YCE)

1. ẸNI ọdun mẹjọ ni Josiah nigbati o bẹ̀rẹ si ijọba; o si jọba li ọdun mọkanlelọgbọ̀n ni Jerusalemu, Orukọ iya rẹ̀ ni Jedida, ọmọbinrin Adaiah ti Boskati.

2. On si ṣe eyiti o tọ́ li oju Oluwa o si rìn li ọ̀na Dafidi baba rẹ̀ gbogbo, kò si yipada si apa ọ̀tún tabi si apa òsi.

3. O si ṣe li ọdun kejidilogun Josiah ọba li ọba rán Ṣafani ọmọ Asaliah ọmọ Mesullamu, akọwe, si ile Oluwa, wipe,

4. Gòke tọ̀ Hilkiah olori alufa lọ, ki o le ṣirò iye fadakà ti a mu wá sinu ile Oluwa, ti awọn olùtọju iloro ti kojọ lọwọ awọn enia:

5. Ẹ si jẹ ki wọn ki o fi le awọn olùṣe iṣẹ na lọwọ, ti nṣe alabojuto ile Oluwa: ki ẹ si jẹ ki wọn ki o fi fun awọn olùṣe iṣẹ na ti mbẹ ninu ile Oluwa, lati tun ibi ẹya ile na ṣe.

6. Fun awọn gbẹnagbẹna, ati fun awọn akọle, ati awọn ọ̀mọle, lati rà ìti-igi ati okuta gbígbẹ lati tún ile na ṣe.

7. Ṣugbọn a kò ba wọn ṣe iṣirò owo ti a fi le wọn lọwọ, nitoriti nwọn ṣe otitọ.

8. Hilkiah olori alufa si sọ fun Ṣafani akọwe pe, Emi ri iwe ofin ni ile Oluwa. Hilkiah si fi iwe na fun Ṣafani, on si kà a.

9. Ṣafani akọwe si wá sọdọ ọba, o si tún mu èsi pada fun ọba wá, o si wipe, Awọn iranṣẹ rẹ ti kó owo na jọ ti a ri ni ile na, nwọn si ti fi le ọwọ awọn ti o nṣiṣẹ na, ti nṣe alabojuto ile Oluwa.