Yorùbá Bibeli

2. A. Ọba 21:21-26 Yorùbá Bibeli (YCE)

21. O si rìn li ọ̀na gbogbo ti baba rẹ̀ rìn, o si sìn awọn ere ti baba rẹ̀ sìn, o si bọ wọn:

22. On si kọ̀ OLUWA Ọlọrun awọn baba rẹ̀ silẹ, kò si rìn li ọ̀na Oluwa.

23. Awọn iranṣẹ Amoni si dìtẹ si i, nwọn si pa ọba ni ile rẹ̀.

24. Awọn enia ilẹ na si pa gbogbo awọn ti o dìtẹ si Amoni ọba: awọn enia ilẹ na si fi Josiah ọmọ rẹ̀ jọba ni ipò rẹ̀.

25. Ati iyokù iṣe Amoni ti o ti ṣe, a kò ha kọ wọn sinu iwe ọ̀rọ ọjọ awọn ọba Juda?

26. A si sìn i ni isà okú rẹ̀ ninu ọgba Ussa: Josiah ọmọ rẹ̀ si jọba ni ipò rẹ̀.