Yorùbá Bibeli

2. A. Ọba 21:18-23 Yorùbá Bibeli (YCE)

18. Manasse si sùn pẹlu awọn baba rẹ̀, a si sin i ninu ọgba-ile rẹ̀, ninu ọgba Ussa: Amoni ọmọ rẹ̀ si jọba ni ipò rẹ̀.

19. Ẹni ọdun mejilelogun ni Amoni nigbati o bẹ̀rẹ si ijọba, o si jọba li ọdun meji ni Jerusalemu. Orukọ iya rẹ̀ ni Mesullemeti, ọmọbinrin Harusi ti Jotba.

20. On si ṣe eyiti o buru li oju Oluwa, bi baba rẹ̀ Manasse ti ṣe.

21. O si rìn li ọ̀na gbogbo ti baba rẹ̀ rìn, o si sìn awọn ere ti baba rẹ̀ sìn, o si bọ wọn:

22. On si kọ̀ OLUWA Ọlọrun awọn baba rẹ̀ silẹ, kò si rìn li ọ̀na Oluwa.

23. Awọn iranṣẹ Amoni si dìtẹ si i, nwọn si pa ọba ni ile rẹ̀.