Yorùbá Bibeli

2. A. Ọba 20:9-15 Yorùbá Bibeli (YCE)

9. Isaiah si wipe, Àmi yi ni iwọ o ni lati ọdọ Oluwa wá, pe, Oluwa yio ṣe nkan yi ti on ti sọ: ki ojiji ki o lọ siwaju ni iṣisẹ̀ mẹwa ni, tabi ki o pada sẹhin ni iṣisẹ̀ mẹwa?

10. Hesekiah si dahùn wipe, Ohun ti o rọrùn ni fun ojiji ki o lọ siwaju ni iṣisẹ̀ mẹwa: bẹ̃kọ, ṣugbọn jẹ ki ojiji ki o pada sẹhin ni iṣisẹ̀ mẹwa.

11. Isaiah woli si kepè Oluwa; on si mu ojiji pada sẹhin ni iṣisẹ̀ mẹwa, nipa eyiti o ti sọ̀kalẹ ninu agogo-õrùn Ahasi.

12. Li akokò na ni Berodaki-Baladani, ọmọ Baladani, ọba Babeli, rán iwe ati ọrẹ si Hesekiah: nitoriti o ti gbọ́ pe Hesekiah ti ṣe aisàn.

13. Hesekiah si fi eti si ti wọn, o si fi gbogbo ile iṣura ohun iyebiye rẹ̀ hàn wọn, fadakà, ati wura, ati turari, ati ororo iyebiye, ati gbogbo ile ohun ihamọra rẹ̀, ati gbogbo eyiti a ri ninu iṣura rẹ̀: kò si nkan ni ile rẹ̀, tabi ni gbogbo ijọba rẹ̀, ti Hesekiah kò fi hàn wọn.

14. Nigbana ni Isaiah woli wá si ọdọ Hesekiah ọba, o si wi fun u pe, Kili awọn ọkunrin wọnyi wi? ati nibo ni nwọn ti wá si ọdọ rẹ? Hesekiah si wipe, Ilu òkere ni nwọn ti wá, ani lati Babeli:

15. On si wipe, Kini nwọn ri ni ile rẹ? Hesekiah si dahùn wipe, Gbogbo nkan ti mbẹ ni ile mi ni nwọn ti ri: kò si nkan ninu iṣura mi ti emi kò fi hàn wọn.