Yorùbá Bibeli

2. A. Ọba 20:12-21 Yorùbá Bibeli (YCE)

12. Li akokò na ni Berodaki-Baladani, ọmọ Baladani, ọba Babeli, rán iwe ati ọrẹ si Hesekiah: nitoriti o ti gbọ́ pe Hesekiah ti ṣe aisàn.

13. Hesekiah si fi eti si ti wọn, o si fi gbogbo ile iṣura ohun iyebiye rẹ̀ hàn wọn, fadakà, ati wura, ati turari, ati ororo iyebiye, ati gbogbo ile ohun ihamọra rẹ̀, ati gbogbo eyiti a ri ninu iṣura rẹ̀: kò si nkan ni ile rẹ̀, tabi ni gbogbo ijọba rẹ̀, ti Hesekiah kò fi hàn wọn.

14. Nigbana ni Isaiah woli wá si ọdọ Hesekiah ọba, o si wi fun u pe, Kili awọn ọkunrin wọnyi wi? ati nibo ni nwọn ti wá si ọdọ rẹ? Hesekiah si wipe, Ilu òkere ni nwọn ti wá, ani lati Babeli:

15. On si wipe, Kini nwọn ri ni ile rẹ? Hesekiah si dahùn wipe, Gbogbo nkan ti mbẹ ni ile mi ni nwọn ti ri: kò si nkan ninu iṣura mi ti emi kò fi hàn wọn.

16. Isaiah si wi fun Hesekiah pe, Gbọ́ ọ̀rọ Oluwa.

17. Kiyesi i, ọjọ mbọ̀, ti a o kó gbogbo nkan ti mbẹ ninu ile rẹ, ati eyiti awọn baba rẹ ti tò jọ titi di oni, lọ si Babeli: ohun kan kì yio kù, li Oluwa wi.

18. Ati ninu awọn ọmọ rẹ ọkunrin ti yio ti inu rẹ jade wá, ti iwọ o bi, ni nwọn o kó lọ; nwọn o si mã ṣe iwẹ̀fa li ãfin ọba Babeli.

19. Nigbana ni Hesekiah wi fun Isaiah pe, Rere li ọ̀rọ Oluwa ti iwọ sọ. On si wipe, kò ha dara bi alafia ati otitọ ba wà lọjọ mi?

20. Ati iyokù iṣe Hesekiah ati gbogbo agbara rẹ̀, ati bi o ti ṣe adagun omi, ati ọ̀na omi na, ti o si mu omi wá sinu ilu, a kò ha kọ wọn sinu iwe ọ̀rọ ọjọ awọn ọba Juda?

21. Hesekiah si sùn pẹlu awọn baba rẹ̀: Manasse ọmọ rẹ̀ si jọba ni ipò rẹ̀.