Yorùbá Bibeli

2. A. Ọba 20:1-6 Yorùbá Bibeli (YCE)

1. LI ọjọ wọnni ni Hesekiah ṣe aisàn de oju-ikú. Isaiah woli ọmọ Amosi si tọ̀ ọ wá, o si wi fun u pe, Bayi li Oluwa wi, Palẹ ile rẹ mọ́; nitoriti iwọ o kú, iwọ kì yio si yè.

2. Nigbana ni o yi oju rẹ̀ pada si ogiri, o si gbadura si Oluwa, wipe,

3. Emi bẹ̀ ọ, Oluwa, ranti nisisiyi bi emi ti rìn niwaju rẹ ninu otitọ ati ninu aiya pipe, ti mo si ti ṣe eyiti o dara li oju rẹ. Hesekiah si sọkún gidigidi.

4. O si ṣe, ki Isaiah ki o to jade si ãrin agbalá-ãfin, li ọ̀rọ Oluwa tọ̀ ọ wá wipe,

5. Tun pada, ki o si wi fun Hesekiah olori awọn enia mi pe, Bayi li Oluwa Ọlọrun Dafidi baba rẹ wi pe, Emi ti gbọ́ adura rẹ, emi si ti ri omije rẹ: kiyesi i, emi o wò ọ sàn: ni ijọ kẹta iwọ o gòke lọ si ile Oluwa.

6. Emi o si bù ọdun mẹ̃dogun kún ọjọ rẹ: emi o si gbà ọ ati ilu yi lọwọ ọba Assiria, emi o si dãbò bò ilu yi, nitori ti emi tikara mi, ati nitori ti Dafidi iranṣẹ mi.