14. Ki iwọ ki o pa ofin mọ́ li ailabawọn, li ailẹgan, titi di ifarahàn Oluwa wa Jesu Kristi:
15. Eyiti yio fihàn ni igba tirẹ̀, Ẹniti iṣe Olubukún ati Alagbara na kanṣoṣo, Ọba awọn ọba, ati Oluwa awọn oluwa;
16. Ẹnikanṣoṣo ti o ni aikú, ti ngbe inu imọlẹ ti a kò le sunmọ, ẹniti enia kan kò ri rí ti kò si le ri: ẹniti ọla ati agbara titi lai iṣe tirẹ. Amin.
17. Kìlọ fun awọn ti o lọrọ̀ li aiye isisiyi, ki nwọn máṣe gberaga, bẹni ki nwọn máṣe gbẹkẹle ọrọ̀ aidaniloju, bikoṣe le Ọlọrun alãye, ti nfi ohun gbogbo fun wa lọpọlọpọ lati lo;
18. Ki nwọn ki o mã ṣõre, ki nwọn ki o mã pọ̀ ni iṣẹ rere, ki nwọn mura lati pin funni, ki nwọn ki o ni ẹmi ibakẹdun;
19. Ki nwọn ki o mã tò iṣura ipilẹ rere jọ fun ara wọn dè igba ti mbọ̀, ki nwọn ki o le di ìye tõtọ mu.
20. Timotiu, ṣọ ohun ni ti a fi si itọju rẹ, yà kuro ninu ọ̀rọ asan ati ijiyan ohun ti a nfi eke pè ni imọ;
21. Eyiti awọn ẹlomiran jẹwọ rẹ̀ ti nwọn si ṣina igbagbọ́. Ki ore-ọfẹ ki o wà pẹlu rẹ. Amin.