Wọnyi si ni olori awọn ọkunrin akọni ti Dafidi ni; awọn ti o fi ara wọn mọ ọ girigiri ni ijọba rẹ̀, pẹlu gbogbo Israeli, lati fi i jọba, gẹgẹ bi ọ̀rọ Oluwa fun Israeli.