A sá tẹ́ nyin lọrùn nisisiyi, a sá ti sọ nyin di ọlọrọ̀ nisisiyi, ẹnyin ti njọba laisi wa: iba si wu mi ki ẹnyin ki o jọba, ki awa ki o le jùmọ jọba pẹlu nyin.