Yorùbá Bibeli

1. Kor 1:28-31 Yorùbá Bibeli (YCE)

28. Ati awọn ohun aiye ti kò niyìn, ati awọn ohun ti a nkẹgàn, li Ọlọrun si ti yàn, ani, awọn ohun ti kò si, lati sọ awọn ohun ti o wà di asan:

29. Ki o máṣe si ẹlẹran-ara ti yio ṣogo niwaju rẹ̀.

30. Ṣugbọn nipasẹ rẹ̀ li ẹnyin wà ninu Kristi Jesu, ẹniti Ọlọrun fi ṣe ọgbọ́n, ati ododo, ati isọdimimọ́, ati idande fun wa:

31. Pe, gẹgẹ bi a ti kọ ọ, Ẹniti o ba nṣogo, ki o mã ṣogo ninu Oluwa.