Yorùbá Bibeli

1. A. Ọba 8:46-52 Yorùbá Bibeli (YCE)

46. Bi nwọn ba ṣẹ̀ si ọ, nitoriti kò si enia kan ti kì iṣẹ̀, bi iwọ ba si binu si wọn, ti o si fi wọn le ọwọ́ ọta, tobẹ̃ ti a si kó wọn lọ ni igbèkun si ilẹ ọta, jijìna tabi nitosi;

47. Bi nwọn ba rò inu ara wọn wò ni ilẹ nibiti a gbe kó wọn ni igbèkun lọ, ti nwọn ba si ronupiwàda, ti nwọn ba si bẹ̀ ọ ni ilẹ awọn ti o kó wọn ni igbèkun lọ, wipe, Awa ti dẹṣẹ, awa ti ṣe ohun ti kò tọ, awa ti ṣe buburu;

48. Bi nwọn ba si fi gbogbo àiya ati gbogbo ọkàn wọn yipada si ọ ni ilẹ awọn ọta wọn, ti o kó wọn ni igbèkun lọ, ti nwọn si gbadura si ọ siha ilẹ wọn, ti iwọ ti fi fun awọn baba wọn, ilu ti iwọ ti yàn, ati ile ti emi kọ́ fun orukọ rẹ:

49. Nigbana ni ki iwọ ki o gbọ́ adura wọn ati ẹ̀bẹ wọn li ọrun ibugbe rẹ, ki o si mu ọ̀ran wọn duro:

50. Ki o si darijì awọn enia rẹ ti o ti dẹṣẹ si ọ, ati gbogbo irekọja wọn ninu eyiti nwọn ṣẹ̀ si ọ, ki o si fun wọn ni ãnu niwaju awọn ti o kó wọn ni igbèkun lọ, ki nwọn ki o le ṣãnu fun wọn.

51. Nitori enia rẹ ati ini rẹ ni nwọn, ti iwọ mu ti Egipti jade wá, lati inu ileru irin:

52. Ki oju rẹ ki o le ṣi si ẹ̀bẹ iranṣẹ rẹ, ati si ẹ̀bẹ Israeli enia rẹ, lati tẹtisilẹ si wọn ninu ohun gbogbo ti nwọn o ke pè ọ si.