Yorùbá Bibeli

1. A. Ọba 20:1-7 Yorùbá Bibeli (YCE)

1. BENHADADI, oba Siria si gbá gbogbo ogun rẹ̀ jọ: ọba mejilelọgbọn si mbẹ pẹlu rẹ̀ ati ẹṣin ati kẹkẹ́: o si gokè lọ, o si dóti Samaria, o ba a jagun.

2. O si rán awọn onṣẹ sinu ilu, sọdọ Ahabu, ọba Ìsraeli, o si wi fun u pe, Bayi ni Benhadadi wi.

3. Fadaka rẹ ati wura rẹ ti emi ni; awọn aya rẹ pẹlu ati awọn ọmọ rẹ, ani awọn ti o dara jùlọ, temi ni nwọn.

4. Ọba Israeli si dahùn o si wipe, oluwa mi, ọba, gẹgẹ bi ọ̀rọ rẹ tirẹ li emi, ati ohun gbogbo ti mo ni.

5. Awọn onṣẹ si tun padà wá, nwọn si wipe, Bayi ni Benhadadi sọ wipe, Mo tilẹ ranṣẹ si ọ wipe, Ki iwọ ki o fi fadaka rẹ ati wura rẹ, ati awọn aya rẹ, ati awọn ọmọ rẹ le mi lọwọ;

6. Nigbati emi ba rán awọn iranṣẹ mi si ọ ni iwòyi ọla, nigbana ni nwọn o wá ile rẹ wò, ati ile awọn iranṣẹ rẹ; yio si ṣe, ohunkohun ti o ba dara loju rẹ, on ni nwọn o fi si ọwọ́ wọn, nwọn o si mu u lọ.

7. Nigbana ni ọba Israeli pè gbogbo awọn àgba ilu, o si wipe, Ẹ fiyèsi i, emi bẹ̀ nyin, ki ẹ si wò bi ọkunrin yi ti nfẹ́ ẹ̀fẹ: nitoriti o ranṣẹ si mi fun awọn aya mi, ati fun awọn ọmọ mi, ati fun fadaka mi, ati fun wura mi, emi kò si fi dù u.