Yorùbá Bibeli

1. A. Ọba 17:1-5 Yorùbá Bibeli (YCE)

1. ELIJAH ara Tiṣbi, lati inu awọn olugbe Gileadi, wi fun Ahabu pe, Bi Oluwa Ọlọrun ti wà, niwaju ẹniti emi duro, kì yio si ìri tabi òjo li ọdun wọnyi, ṣugbọn gẹgẹ bi ọ̀rọ mi.

2. Ọrọ Oluwa si tọ̀ ọ wá wipe:

3. Kuro nihin, ki o si kọju siha ila-õrun, ki o si fi ara rẹ pamọ nibi odò Keriti, ti mbẹ niwaju Jordani.

4. Yio si ṣe, iwọ o mu ninu odò na; mo si ti paṣẹ fun awọn ẹiyẹ iwò lati ma bọ́ ọ nibẹ.

5. O si lọ, o si ṣe gẹgẹ bi ọ̀rọ Oluwa: o si lọ, o si ngbe ẹ̀ba odò Keriti, ti mbẹ niwaju Jordani.