Yorùbá Bibeli

1. A. Ọba 15:31-33 Yorùbá Bibeli (YCE)

31. Ati iyokù iṣe Nadabu, ati gbogbo ohun ti o ṣe, a kò ha kọ wọn sinu iwe ọ̀rọ ọjọ awọn ọba Israeli.

32. Ogun si wà, lãrin Asa ati Baaṣa ọba Israeli ni gbogbo ọjọ wọn.

33. Li ọdun kẹta Asa, ọba Juda, ni Baaṣa, ọmọ Ahijah bẹ̀rẹ si ijọba lori gbogbo Israeli ni Tirsa, li ọdun mẹrinlelogun.