Nitorina, kiyesi i, emi o mu ibi wá si ile Jeroboamu, emi o ke gbogbo ọdọmọkunrin kuro lọdọ Jeroboamu, ati ọmọ-ọdọ ati omnira ni Israeli, emi o si mu awọn ti o kù ni ile Jeroboamu kuro, gẹgẹ bi enia ti ikó igbẹ kuro, titi gbogbo rẹ̀ yio fi tan.