Yorùbá Bibeli

Hag 2:1-13 Yorùbá Bibeli (YCE)

1. LI oṣù keje, li ọjọ kọkanlelogun oṣù na, ni ọ̀rọ Oluwa wá nipa ọwọ́ Hagai woli, wipe,

2. Sọ nisisiyi fun Serubbabeli ọmọ Ṣealtieli, bãlẹ Juda, ati fun Joṣua, ọmọ Josedeki, olori alufa, ati fun awọn enia iyokù pe,

3. Tali o kù ninu nyin ti o ti ri ile yi li ogo rẹ̀ akọṣe? bawo li ẹnyin si ti ri i si nisisiyi? kò ha dàbi asan loju nyin bi a fi ṣe akawe rẹ̀?

4. Ṣugbọn nisisiyi mura giri, Iwọ Serubbabeli, li Oluwa wi, ki o si mura giri, Iwọ Joṣua, ọmọ Josedeki, olori alufa; ẹ si mura giri gbogbo ẹnyin enia ilẹ na, li Oluwa wi, ki ẹ si ṣiṣẹ: nitori emi wà pẹlu nyin, li Oluwa awọn ọmọ-ogun wi.

5. Gẹgẹ bi ọ̀rọ ti mo ba nyin dá majẹmu nigbati ẹnyin ti Egipti jade wá, bẹ̃ni ẹmi mi wà lãrin nyin: ẹ máṣe bẹ̀ru.

6. Nitori bayi ni Oluwa awọn ọmọ-ogun wi, pe, Ẹ̃kan ṣa, nigbà diẹ si i, li emi o mì awọn ọrun, ati aiye, ati okun, ati iyàngbẹ ilẹ.

7. Emi o si mì gbogbo orilẹ-ède, ifẹ gbogbo orilẹ-ède yio si de: emi o si fi ogo kún ile yi, li Oluwa awọn ọmọ-ogun wi.

8. Temi ni fàdakà, temi si ni wurà, li Oluwa awọn ọmọ-ogun wi.

9. Ogo ile ikẹhìn yi yio pọ̀ jù ti iṣãju lọ, li Oluwa awọn ọmọ-ogun wi: nihinyi li emi o si fi alafia fun ni, li Oluwa awọn ọmọ-ogun wi.

10. Li ọjọ ikẹrinlelogun oṣù kẹsan, li ọdun keji Dariusi, li ọ̀rọ Oluwa wá nipa Hagai woli, pe,

11. Bayi li Oluwa awọn ọmọ-ogun wi; bère ofin lọwọ awọn alufa nisisiyi, pe,

12. Bi ẹnikan ba rù ẹran mimọ́ ni iṣẹti aṣọ rẹ̀, ti o si fi iṣẹti aṣọ rẹ̀ kan àkara, tabi àṣaró, tabi ọti-waini, tabi ororo, tabi ẹrankẹran, yio ha jẹ mimọ́? Awọn alufa si dahùn wipe, Bẹ̃kọ.

13. Hagai si wipe, Bi ẹnikan ti o ba jẹ alaimọ́ nipa okú ba fi ara kan ọkan ninu wọnyi, yio ha jẹ alaimọ́? Awọn alufa si dahùn wipe, Yio jẹ alaimọ́.