Yorùbá Bibeli

Hag 1:10-15 Yorùbá Bibeli (YCE)

10. Nitorina ni a ṣe dá ìri ọrun duro lori nyin, a si da eso ilẹ duro.

11. Mo si ti pè ọdá sori ilẹ, ati sori oke-nla, ati sori ọkà ati sori ọti-waini titún, ati sori ororo, ati sori ohun ti ilẹ mu jade, ati sori enia, ati sori ẹran, ati sori gbogbo iṣẹ ọwọ ẹni.

12. Nigbana ni Serubbabeli ọmọ Ṣealtieli, ati Joṣua ọmọ Josedeki, olori alufa, pẹlu gbogbo enia iyokù, gba ohùn Oluwa Ọlọrun wọn gbọ́, ati ọ̀rọ Hagai woli, gẹgẹ bi Oluwa Ọlọrun wọn ti rán a, awọn enia si bẹ̀ru niwaju Oluwa.

13. Nigbana ni Hagai iranṣẹ Oluwa jiṣẹ Oluwa fun awọn enia pe, Emi wà pẹlu nyin, li Oluwa wi.

14. Oluwa si rú ẹ̀mi Serubbabeli ọmọ Ṣealtieli, bãlẹ Juda soke, ati ẹmi Joṣua ọmọ Josedeki, olori alufa, ati ẹmi gbogbo awọn enia iyokù; nwọn si wá nwọn si ṣiṣẹ ni ile Oluwa awọn ọmọ-ogun Ọlọrun wọn.

15. Li ọjọ kẹrinlelogun oṣù kẹfà, li ọdun keji Dariusi ọba.