Yorùbá Bibeli

Esr 8:5-19 Yorùbá Bibeli (YCE)

5. Ninu awọn ọmọ Ṣekaniah; ọmọ Jahasieli, ati pẹlu rẹ̀, ọdunrun ọkunrin.

6. Ninu awọn ọmọ Adini pẹlu, Ebedi ọmọ Jonatani, ati pẹlu rẹ̀, ãdọta ọkunrin.

7. Ati ninu awọn ọmọ Elamu; Jeṣaiah ọmọ Ataliah, ati pẹlu rẹ̀, ãdọrin ọkunrin.

8. Ati ninu awọn ọmọ Ṣefatiah; Sebadiah ọmọ Mikaeli, ati pẹlu rẹ̀, ọgọrin ọkunrin.

9. Ninu awọn ọmọ Joabu; Obadiah ọmọ Jahieli ati pẹlu rẹ̀, ogunlugba ọkunrin o din meji.

10. Ati ninu awọn ọmọ Ṣelomiti; ọmọ Josafiah, ati pẹlu rẹ̀, ọgọjọ ọkunrin.

11. Ati ninu awọn ọmọ Bebai; Sekariah, ọmọ Bebai, ati pẹlu rẹ̀, ọkunrin mejidilọgbọn.

12. Ati ninu awọn ọmọ Asgadi; Johanani ọmọ Hakkatani, ati pẹlu rẹ̀, ãdọfa ọkunrin.

13. Ati ninu awọn ọmọ ikẹhin Adonikamu, orukọ awọn ẹniti iṣe wọnyi, Elifeleti, Jeieli, ati Ṣemaiah, ati pẹlu wọn, ọgọta ọkunrin.

14. Ninu awọn ọmọ Bigfai pẹlu; Uttai, ati Sabbudi, ati pẹlu wọn, ãdọrin ọkunrin.

15. Mo si kó wọn jọ pọ li eti odò ti o ṣàn si Ahafa; nibẹ li a si gbe inu agọ li ọjọ mẹta: mo si wò awọn enia rere pẹlu awọn alufa, emi kò si ri ẹnikan ninu awọn ọmọ Lefi nibẹ.

16. Nigbana ni mo ranṣẹ pè Elieseri, Arieli, Ṣemaiah, ati Elnatani ati Jaribi, ati Elnatani, ati Natani, ati Sekariah, ati Meṣullamu, awọn olori pẹlu Joiaribi, ati Elnatani, enia oloye.

17. Mo si rán wọn ti awọn ti aṣẹ si ọdọ Iddo, olori ni ibi Kasifia, mo si kọ́ wọn li ohun ti nwọn o wi fun Iddo, ati fun awọn arakunrin rẹ̀, awọn Netinimu ni ibi Kasifia, ki nwọn ki o mu awọn iranṣẹ wá si ọdọ wa fun ile Ọlọrun wa.

18. Ati nipa ọwọ rere Ọlọrun wa lara wa, nwọn mu ọkunrin oloye kan fun wa wá, ninu awọn ọmọ Mali, ọmọ Lefi, ọmọ Israeli; ati Ṣerebiah, pẹlu awọn ọmọ rẹ̀ ati awọn arakunrin rẹ̀, mejidilogun.

19. Ati Haṣabiah, ati pẹlu rẹ̀ Jeṣaiah, ninu awọn ọmọ Merari, awọn arakunrin rẹ̀ pẹlu awọn ọmọ wọn, ogún;