Yorùbá Bibeli

Esr 8:25-36 Yorùbá Bibeli (YCE)

25. Mo si wọ̀n fàdaka ati wura fun wọn, ati ohun èlo, ani ọrẹ ti iṣe ti ile Ọlọrun wa, ti ọba ati awọn ìgbimọ rẹ̀ ati awọn ijoye rẹ̀, ati gbogbo Israeli ti o wà nibẹ, ta li ọrẹ:

26. Mo si wọ̀n ãdọtalelẹgbẹta talenti fàdaka le wọn li ọwọ, ati ohun èlo fàdaka, ọgọrun talenti, ati ti wura, ọgọrun talenti,

27. Pẹlu ogun ago wura ẹlẹgbẹgbẹrun dramu, ati ohun èlo meji ti bàba daradara, ti o niye lori bi wura.

28. Mo si wi fun wọn pe, Mimọ́ li ẹnyin si Oluwa; mimọ́ si li ohun èlo wọnyi; ọrẹ atinuwa si Oluwa Ọlọrun awọn baba nyin ni fàdaka ati wura na.

29. Ẹ ma tọju wọn, ki ẹ si ma pa wọn mọ, titi ẹnyin o fi wọ̀n wọn niwaju awọn olori ninu awọn alufa ati ọmọ Lefi, pẹlu awọn olori ninu awọn baba Israeli ni Jerusalemu, ninu iyàrá ile Oluwa.

30. Bẹ̃ni awọn alufa ati awọn ọmọ Lefi mu fàdaka ati wura ti a wọ̀n pẹlu ohun-èlo wọnni lati ko wọn wá si Jerusalemu, sinu ile Ọlọrun wa.

31. Nigbana ni awa lọ kuro ni odò Ahafa, li ọjọ ekejila oṣu ikini, lati lọ si Jerusalemu: ọwọ Ọlọrun wa si wà lara wa, o si gba wa lọwọ awọn ọta, ati lọwọ iru awọn ti o ba ni ibuba li ọ̀na.

32. Awa si de Jerusalemu, awa si simi nibẹ li ọjọ mẹta.

33. Li ọjọ ẹkẹrin li a wọ̀n fàdaka ati wura ati ohun-èlo wọnni ninu ile Ọlọrun wa si ọwọ Meremoti ọmọ Uriah, alufa, ati pẹlu rẹ̀ ni Eleasari ọmọ Finehasi; ati pẹlu wọn ni Josabadi ọmọ Jeṣua, ati Noadia, ọmọ Binnui, awọn ọmọ Lefi;

34. Nipa iye, ati nipa ìwọn ni gbogbo wọn: a si kọ gbogbo ìwọn na sinu iwe ni igbana.

35. Ọmọ awọn ti a ti ko lọ, awọn ti o ti inu igbekùn pada bọ̀, ru ẹbọ sisun si Ọlọrun Israeli, ẹgbọrọ malu mejila, àgbo mẹrindilọgọrun, ọdọ-agutan mẹtadilọgọrin, ati obukọ mejila fun ẹbọ ẹ̀ṣẹ: gbogbo eyi jẹ ẹbọ sisun si Oluwa.

36. Nwọn si fi aṣẹ ọba fun awọn ijoye ọba, ati fun awọn balẹ ni ihahin odò: nwọn si ràn awọn enia na lọwọ, ati ile Ọlọrun.