Yorùbá Bibeli

Esr 8:21-29 Yorùbá Bibeli (YCE)

21. Nigbana ni mo kede àwẹ kan nibẹ lẹba odò Ahafa, ki awa ki o le pọn ara wa loju niwaju Ọlọrun wa, lati ṣafẹri ọ̀na titọ́ fun wa li ọwọ rẹ̀, ati fun ọmọ wẹrẹ wa, ati fun gbogbo ini wa.

22. Nitoripe, oju tì mi lati bère ẹgbẹ ọmọ-ogun li ọwọ ọba, ati ẹlẹṣin, lati ṣọ wa nitori awọn ọta li ọ̀na: awa sa ti sọ fun ọba pe, Ọwọ Ọlọrun wa mbẹ lara awọn ti nṣe afẹri rẹ̀ fun rere; ṣugbọn agbara rẹ̀ ati ibinu rẹ̀ mbẹ lara gbogbo awọn ti o kọ̀ ọ silẹ.

23. Bẹ̃li awa gbàwẹ, ti awa si bẹ̀ Ọlọrun wa nitori eyi: on si gbọ́ ẹ̀bẹ wa.

24. Nigbana ni mo yàn ẹni-mejila si ọ̀tọ ninu awọn olori awọn alufa, Ṣerebiah, Haṣabiah, ati mẹwa ninu awọn arakunrin wọn pẹlu wọn,

25. Mo si wọ̀n fàdaka ati wura fun wọn, ati ohun èlo, ani ọrẹ ti iṣe ti ile Ọlọrun wa, ti ọba ati awọn ìgbimọ rẹ̀ ati awọn ijoye rẹ̀, ati gbogbo Israeli ti o wà nibẹ, ta li ọrẹ:

26. Mo si wọ̀n ãdọtalelẹgbẹta talenti fàdaka le wọn li ọwọ, ati ohun èlo fàdaka, ọgọrun talenti, ati ti wura, ọgọrun talenti,

27. Pẹlu ogun ago wura ẹlẹgbẹgbẹrun dramu, ati ohun èlo meji ti bàba daradara, ti o niye lori bi wura.

28. Mo si wi fun wọn pe, Mimọ́ li ẹnyin si Oluwa; mimọ́ si li ohun èlo wọnyi; ọrẹ atinuwa si Oluwa Ọlọrun awọn baba nyin ni fàdaka ati wura na.

29. Ẹ ma tọju wọn, ki ẹ si ma pa wọn mọ, titi ẹnyin o fi wọ̀n wọn niwaju awọn olori ninu awọn alufa ati ọmọ Lefi, pẹlu awọn olori ninu awọn baba Israeli ni Jerusalemu, ninu iyàrá ile Oluwa.